Owe 29:1-14

Owe 29:1-14 YBCV

ẸNITI a ba mbawi ti o wà ọrùn kì, yio parun lojiji, laisi atunṣe. Nigbati awọn olododo wà lori oyè, awọn enia a yọ̀; ṣugbọn nigbati enia buburu ba gori oyè, awọn enia a kẹdùn. Ẹnikẹni ti o fẹ ọgbọ́n, a mu baba rẹ̀ yọ̀: ṣugbọn ẹniti o mba panṣaga kẹgbẹ, a ba ọrọ̀ rẹ̀ jẹ. Nipa idajọ li ọba imu ilẹ tòro: ṣugbọn ẹniti o ba ngbà ọrẹ a bì i ṣubu. Ẹniti o npọ́n ẹnikeji rẹ̀ ta àwọn silẹ fun ẹsẹ rẹ̀. Ninu irekọja enia ibi, ikẹkùn mbẹ: ṣugbọn olododo a ma kọrin, a si ma yọ̀. Olododo a ma rò ọ̀ran talaka: ṣugbọn enia buburu kò ṣú si i lati rò o. Awọn ẹlẹgàn enia da irukerudo si ilu: ṣugbọn awọn ọlọgbọ́n enia ṣẹ́ri ibinu kuro. Ọlọgbọ́n enia ti mba aṣiwère enia ja, bi inu li o mbi, bi ẹrín li o nrín, isimi kò si. Awọn enia-ẹ̀jẹ korira aduro-ṣinṣin: ṣugbọn awọn olododo a ma ṣe afẹri ọkàn rẹ̀. Aṣiwère a sọ gbogbo inu rẹ̀ jade: ṣugbọn ọlọgbọ́n a pa a mọ́ di ìgba ikẹhin. Bi ijoye ba feti si ọ̀rọ-eke, gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ ni yio buru. Talaka ati aninilara enia pejọ pọ̀: Oluwa li o ntan imọlẹ si oju awọn mejeji. Ọba ti o fi otitọ ṣe idajọ talaka, itẹ́ rẹ̀ yio fi idi mulẹ lailai.