Owe 28:15-28

Owe 28:15-28 YBCV

Bi kiniun ti nke ramùramu, ati ẹranko beari ti nfi ebi sare kiri; bẹ̃ni ẹni buburu ti o joye lori awọn talaka. Ọmọ-alade ti o ṣe alaimoye pupọ ni iṣe ìwa-ika pupọ pẹlu: ṣugbọn eyiti o korira ojukokoro yio mu ọjọ rẹ̀ pẹ. Enia ti o ba hù ìwa-ika si ẹ̀jẹ ẹnikeji, yio sá lọ si ihò: ki ẹnikan ki o máṣe mu u. Ẹnikẹni ti o ba nrin dẽde ni yio là: ṣugbọn ẹniti o nfi ayidayida rìn loju ọ̀na meji, yio ṣubu ninu ọkan ninu wọn. Ẹniti o ba ro ilẹ rẹ̀ yio li ọ̀pọ onjẹ: ṣugbọn ẹniti o ba ntọ̀ enia asan lẹhin yio ni òṣi to. Olõtọ enia yio pọ̀ fun ibukún: ṣugbọn ẹniti o kanju ati là kì yio ṣe alaijiya. Iṣojuṣãju enia kò dara: nitoripe fun òkele onjẹ kan, ọkunrin na yio ṣẹ̀. Ẹniti o kanju ati là, o li oju ilara, kò si rò pe òṣi mbọ̀wá ta on. Ẹniti o ba enia wi yio ri ojurere ni ikẹhin jù ẹniti nfi ahọn pọn ọ lọ. Ẹnikẹni ti o ba nja baba tabi iya rẹ̀ li ole, ti o si wipe, kì iṣe ẹ̀ṣẹ; on na li ẹgbẹ apanirun. Ẹniti o ṣe agberaga li aiya, a rú ìja soke, ṣugbọn ẹniti o gbẹkẹ rẹ̀ le Oluwa li a o mu sanra. Ẹniti o gbẹkẹ le aiya ara rẹ̀, aṣiwère ni; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba nfi ọgbọ́n rìn, on li a o gbà la. Ẹniti o ba nfi fun olupọnju kì yio ṣe alaini: ṣugbọn ẹniti o mu oju rẹ̀ kuro, yio gbà egún pupọ. Nigbati enia buburu ba hù, awọn enia a sá pamọ́: ṣugbọn nigbati nwọn ba ṣegbe, awọn olododo a ma pọ̀ si i.