Owe 27:7-27

Owe 27:7-27 YBCV

Ọkàn ti o yó fi ẹsẹ tẹ afara-oyin; ṣugbọn ọkàn ti ebi npa, ohun kikoro gbogbo li o dùn. Bi ẹiyẹ ti ima fò kiri lati inu itẹ́ rẹ̀, bẹ̃li enia ti o nrìn kiri jina si ipò rẹ̀. Ororo ati turari mu ọkàn dùn: bẹ̃ni adùn ọrẹ ẹni nipa ìgbimọ atọkànwa. Ọrẹ́ rẹ ati ọrẹ́ baba rẹ, máṣe kọ̀ silẹ, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe lọ si ile arakunrin li ọjọ idãmu rẹ: nitoripe aladugbo ti o sunmọ ni, o san jù arakunrin ti o jina rere lọ. Ọmọ mi, ki iwọ ki o gbọ́n, ki o si mu inu mi dùn; ki emi ki o le da ẹniti ngàn mi lohùn. Amoye enia ri ibi tẹlẹ, o si pa ara rẹ̀ mọ́; ṣugbọn awọn òpe kọja a si jẹ wọn niya. Gbà aṣọ rẹ̀ nitoriti o ṣe onigbọwọ alejo, si gbà ohun ẹri lọwọ rẹ̀ fun ajeji obinrin. Ẹniti o ba ndide ni kutukutu ti o nfi ohùn rara kí ọrẹ́ rẹ̀, egún li a o kà a si fun u. Ọṣọrọ-òjo li ọjọ òjo, ati onija obinrin, bakanna ni. Ẹnikẹni ti o pa a mọ́, o pa ẹfũfu mọ́, ororo ọwọ-ọtún rẹ̀ yio si fihàn. Irin a ma pọn irin: bẹ̃li ọkunrin ipọn oju ọrẹ́ rẹ̀. Ẹnikẹni ti o tọju igi-ọpọtọ yio jẹ eso rẹ̀; bẹ̃li ẹniti o duro tì oluwa rẹ̀ li a o buyì fun. Bi oju ti ikò oju li omi, bẹ̃li aiya enia si enia. Ipò-okú ati iparun kì ikún, bẹ̃ni kì isu oju enia. Bi koro fun fadaka, ati ileru fun wura, bẹ̃li enia si iyìn rẹ̀. Bi iwọ tilẹ fi ọmọri-odó gún aṣiwère ninu odo larin alikama, wère rẹ̀ kì yio fi i silẹ. Iwọ ma ṣaniyan ati mọ̀ ìwa agbo-ẹran rẹ, ki iwọ ki o si bojuto awọn ọwọ-ẹran rẹ. Nitoripe ọrọ̀ ki iwà titi lai: ade a ha si ma wà de irandiran? Koriko yọ, ati ọmunú koriko fi ara han, ati ewebẹ̀ awọn òke kojọ pọ̀. Awọn ọdọ-agutan ni fun aṣọ rẹ, awọn obukọ si ni iye-owo oko. Iwọ o si ni wàra ewurẹ to fun onjẹ rẹ, fun onjẹ awọn ara ile rẹ, ati fun onjẹ awọn iranṣẹ-birin rẹ.