Ọmọ mi, ki iwọ ki o gbọ́n, ki o si mu inu mi dùn; ki emi ki o le da ẹniti ngàn mi lohùn. Amoye enia ri ibi tẹlẹ, o si pa ara rẹ̀ mọ́; ṣugbọn awọn òpe kọja a si jẹ wọn niya. Gbà aṣọ rẹ̀ nitoriti o ṣe onigbọwọ alejo, si gbà ohun ẹri lọwọ rẹ̀ fun ajeji obinrin. Ẹniti o ba ndide ni kutukutu ti o nfi ohùn rara kí ọrẹ́ rẹ̀, egún li a o kà a si fun u. Ọṣọrọ-òjo li ọjọ òjo, ati onija obinrin, bakanna ni. Ẹnikẹni ti o pa a mọ́, o pa ẹfũfu mọ́, ororo ọwọ-ọtún rẹ̀ yio si fihàn. Irin a ma pọn irin: bẹ̃li ọkunrin ipọn oju ọrẹ́ rẹ̀. Ẹnikẹni ti o tọju igi-ọpọtọ yio jẹ eso rẹ̀; bẹ̃li ẹniti o duro tì oluwa rẹ̀ li a o buyì fun. Bi oju ti ikò oju li omi, bẹ̃li aiya enia si enia.
Kà Owe 27
Feti si Owe 27
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Owe 27:11-19
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò