Owe 27:1-6

Owe 27:1-6 YBCV

MÁṢE leri ara rẹ niti ọjọ ọla, nitoriti iwọ kò mọ̀ ohun ti ọjọ kan yio hù jade. Jẹ ki ẹlomiran ki o yìn ọ, ki o máṣe ẹnu ara rẹ; alejo, ki o má si ṣe ète ara rẹ. Okuta wuwo, yanrin si wuwo, ṣugbọn ibinu aṣiwère, o wuwo jù mejeji lọ. Ibinu ni ìka, irunu si ni kikún-omi; ṣugbọn tani yio duro niwaju owú. Ibawi nigbangba, o san jù ifẹ ti o farasin lọ. Otitọ li ọgbẹ ọrẹ́: ṣugbọn ifẹnukonu ọta li ẹ̀tan.