Máṣe da aṣiwère lohùn gẹgẹ bi wère rẹ̀, ki iwọ pãpa ki o má ba dabi rẹ̀.
Da aṣiwère lohùn gẹgẹ bi wère rẹ̀, ki on ki o má ba gbọ́n li oju ara rẹ̀.
Ẹniti o rán iṣẹ nipa ọwọ aṣiwère, o ke ẹsẹ ara rẹ̀ kuro, o si jẹ ara rẹ̀ niya.
Bi ẹsẹ mejeji ti rọ̀ silẹ lara amukun, bẹ̃li owe li ẹnu awọn aṣiwère.
Bi ẹniti o fi àpo okuta iyebiye sinu okiti okuta, bẹ̃li ẹniti nfi ọlá fun aṣiwère.
Bi ẹgún ti igún ọmuti lọwọ, bẹ̃li owe li ẹnu awọn aṣiwère.
Bi tafatafa ti o mu gbogbo enia gbọgbẹ, bẹ̃ni ẹniti o gbà aṣiwère si iṣẹ, ti o si gba awọn olurekọja si iṣẹ-owo.
Bi aja ti ipada sinu ẽbì rẹ̀, bẹ̃li aṣiwère itun pada sinu wère rẹ̀.
Iwọ ri ẹnikan ti o gbọ́n li oju ara rẹ̀? ireti mbẹ fun aṣiwère jù fun u lọ.
Ọlẹ enia wipe, Kiniun mbẹ li ọ̀na; kiniun mbẹ ni igboro.
Bi ilẹkun ti iyi lori ìwakun rẹ̀, bẹ̃li ọlẹ lori ẹní rẹ̀.
Ọlẹ pa ọwọ rẹ̀ mọ́ sinu iṣãsun; kò si le yọ ọ jade pada wá si ẹnu rẹ̀.
Ọlẹ gbọ́n li oju ara rẹ̀ jù enia meje lọ ti nwọn le fi ọgbọ́n dahùn ọ̀ran.
Ẹniti nkọja lọ, ti o si dasi ìja ti kì iṣe tirẹ̀, o dabi ẹniti o mu ajá leti.
Bi asiwin ti nsọ ọ̀kọ, ọfa ati ikú,
Bẹ̃li ẹniti o tan ẹnikeji rẹ̀ jẹ, ti o si wipe, Iré ha kọ li emi nṣe?
Nigbati igi tan, ina a kú, bẹ̃ni nigbati olofofo kò si, ìja a da.
Bi ẹyin ti ri si ẹyin-iná, ati igi si iná; bẹ̃li enia onijà lati da ìja silẹ.
Ọ̀rọ olofofo dabi adidùn, nwọn a si wọ isalẹ inu lọ.
Ete jijoni, ati aiya buburu, dabi idarọ fadaka ti a fi bò ìkoko.
Ẹniti o ba korira, ti o fi ète rẹ̀ ṣe agabagebe, yio si pa ẹ̀tan mọ́ ninu rẹ̀.
Nigbati o ba sọ̀rọ daradara, máṣe gbà a gbọ́: nitoripe irira meje li o wà li aiya rẹ̀,
Ẹniti a fi ẹ̀tan bò irira rẹ̀ mọlẹ, ìwa-buburu rẹ̀ li a o fi hàn niwaju gbogbo ijọ:
Ẹnikẹni ti o ba wà ihò yio ṣubu sinu rẹ̀: ẹniti o ba si nyi okuta, on ni yio pada tọ̀.
Ahọn eke korira awọn ti a fi njẹniya; ẹnu ipọnni a si ma ṣiṣẹ iparun.