Owe 26:1-2

Owe 26:1-2 YBCV

BI òjo-didì ni ìgba ẹrun, ati bi òjo ni ìgba ikore, bẹ̃li ọlá kò yẹ fun aṣiwère. Bi ẹiyẹ fun iṣikiri, ati alapandẹdẹ fun fifò, bẹ̃ni egún kì yio wá lainidi.