WỌNYI pẹlu li owe Solomoni, ti awọn ọkunrin Hesekiah, ọba Judah kọ silẹ. Ogo Ọlọrun ni lati pa ọ̀ran mọ́: ṣugbọn ọlá awọn ọba ni lati wadi ọ̀ran. Ọrun fun giga, ati ilẹ fun jijin bẹ̃ni a kò le iwadi aiya awọn ọba. Mu idarọ kuro ninu fadaka, ohun-elo yio si jade fun alagbẹdẹ fadaka. Mu enia buburu kuro niwaju ọba, a o si fi idi itẹ́ rẹ̀ kalẹ ninu ododo. Máṣe ṣefefe niwaju ọba, má si ṣe duro ni ipò awọn enia nla. Nitoripe, o san ki a wi fun ọ pe, wá soke nihin, jù ki a fà ọ tì sẹhin niwaju ọmọ-alade ti oju rẹ ti ri. Máṣe jade lọ kankan lati jà, ki iwọ ki o má ba ṣe alaimọ̀ eyiti iwọ o ṣe li opin rẹ̀, nigbati aladugbo rẹ yio dojutì ọ. Ba ẹnikeji rẹ ja ìja rẹ̀; ṣugbọn aṣiri ẹlomiran ni iwọ kò gbọdọ fihàn. Ki ẹniti o ba gbọ́ ki o má ba dojuti ọ, ẹ̀gan rẹ kì yio si lọ kuro lai. Bi eso igi wura ninu agbọ̀n fadaka, bẹ̃ni ọ̀rọ ti a sọ li akoko rẹ̀. Bi oruka wura ati ohun ọṣọ́ wura daradara, bẹ̃li ọlọgbọ́n olubaniwi li eti igbọràn. Bi otutu òjo-didì ni ìgba ikore, bẹ̃ni olõtọ ikọ̀ si awọn ti o rán a: nitoriti o tù awọn oluwa rẹ̀ ninu. Ẹnikẹni ti o ba ṣefefe ninu ẹ̀bun ẹ̀tan, o dabi awọsanma ati afẹfẹ ti kò ni òjo.
Kà Owe 25
Feti si Owe 25
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Owe 25:1-14
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò