Owe 24:30-34

Owe 24:30-34 YBCV

Mo kọja lọ li oko ọlẹ, ati lẹba ọgbà-ajara ẹniti oye kù fun: Si kiyesi i, ẹgún kún bo gbogbo rẹ̀, igbó si bo oju rẹ̀, iganna okuta rẹ̀ si wo lulẹ. Nigbana ni mo ri, mo si fi ọkàn mi si i gidigidi: mo wò o, mo si gbà ẹkọ́. Orun diẹ si i, õgbe diẹ, ikawọkòpọ lati sùn diẹ. Bẹ̃li òṣi rẹ yio de bi ẹniti nrìn; ati aini rẹ bi ọkunrin ti o hamọra ogun.