Máṣe yọ̀ nigbati ọta rẹ ba ṣubu, má si ṣe jẹ ki inu rẹ ki o dùn nigbati o ba kọsẹ̀: Ki Oluwa ki o má ba ri i, ki o si buru li oju rẹ̀, on a si yi ibinu rẹ̀ pada kuro lori rẹ̀. Máṣe ilara si awọn enia buburu, má si ṣe jowu enia buburu. Nitoripe, ère kì yio si fun enia ibi; fitila enia buburu li a o pa. Ọmọ mi, iwọ bẹ̀ru Oluwa ati ọba: ki iwọ ki o má si ṣe dàpọ mọ awọn ti nṣe ayidayida. Nitoripe wàhala wọn yio dide lojiji, ati iparun awọn mejeji, tali o mọ̀ ọ! Wọnyi pẹlu ni ọ̀rọ awọn ọlọgbọ́n. Kò dara lati ṣe ojuṣãju ni idajọ. Ẹniti o ba wi fun enia buburu pe, olododo ni iwọ; on ni awọn enia yio bú, awọn orilẹ-ède yio si korira rẹ̀. Ṣugbọn awọn ti o ba a wi ni yio ni inu-didùn, ibukún rere yio si bọ̀ sori wọn. Yio dabi ẹniti o ṣe ifẹnukonu: ẹniti o ba ṣe idahùn rere. Mura iṣẹ rẹ silẹ lode, ki o si fi itara tulẹ li oko rẹ; nikẹhin eyi, ki o si kọ́ ile rẹ. Máṣe ẹlẹri si ẹnikeji rẹ lainidi: ki iwọ ki o má si ṣe fi ète rẹ ṣẹ̀tan. Máṣe wipe, bẹ̃li emi o ṣe si i, gẹgẹ bi o ti ṣe si mi: emi o san a fun ọkunrin na gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀. Mo kọja lọ li oko ọlẹ, ati lẹba ọgbà-ajara ẹniti oye kù fun: Si kiyesi i, ẹgún kún bo gbogbo rẹ̀, igbó si bo oju rẹ̀, iganna okuta rẹ̀ si wo lulẹ. Nigbana ni mo ri, mo si fi ọkàn mi si i gidigidi: mo wò o, mo si gbà ẹkọ́. Orun diẹ si i, õgbe diẹ, ikawọkòpọ lati sùn diẹ. Bẹ̃li òṣi rẹ yio de bi ẹniti nrìn; ati aini rẹ bi ọkunrin ti o hamọra ogun.
Kà Owe 24
Feti si Owe 24
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Owe 24:17-34
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò