Owe 23:22-25

Owe 23:22-25 YBCV

Fetisi ti baba rẹ ti o bi ọ, má si ṣe gàn iya rẹ, nigbati o ba gbó. Ra otitọ, ki o má si ṣe tà a; ọgbọ́n pẹlu ati ẹkọ́, ati imoye. Baba olododo ni yio yọ̀ gidigidi: ẹniti o si bi ọmọ ọlọgbọ́n, yio ni ayọ̀ ninu rẹ̀. Baba rẹ ati iya rẹ yio yọ̀, inu ẹniti o bi ọ yio dùn.