Máṣe jẹ ki aiya rẹ ki o ṣe ilara si awọn ẹ̀lẹṣẹ, ṣugbọn ki iwọ ki o wà ni ibẹ̀ru Oluwa, li ọjọ gbogbo.
Nitoripe ikẹhin mbẹ nitõtọ; ireti rẹ kì yio si ke kuro.
Gbọ́, iwọ ọmọ mi, ki iwọ ki o si gbọ́n, ki iwọ ki o si ma tọ́ aiya rẹ si ọ̀na titọ.
Máṣe wà ninu awọn ọmuti; ninu awọn ti mba ẹran-ara awọn tikarawọn jẹ.
Nitoripe ọmuti ati ọjẹun ni yio di talaka; ọlẹ ni yio si fi akisa bò ara rẹ̀.
Fetisi ti baba rẹ ti o bi ọ, má si ṣe gàn iya rẹ, nigbati o ba gbó.
Ra otitọ, ki o má si ṣe tà a; ọgbọ́n pẹlu ati ẹkọ́, ati imoye.
Baba olododo ni yio yọ̀ gidigidi: ẹniti o si bi ọmọ ọlọgbọ́n, yio ni ayọ̀ ninu rẹ̀.
Baba rẹ ati iya rẹ yio yọ̀, inu ẹniti o bi ọ yio dùn.
Ọmọ mi, fi aiya rẹ fun mi, ki o si jẹ ki oju rẹ ki o ni inu-didùn si ọ̀na mi.
Nitoripe agbere, iho jijin ni; ati ajeji obinrin, iho hiha ni.
On a si ba ni ibuba bi ole, a si sọ awọn olurekọja di pupọ ninu awọn enia.
Tali o ni òṣi? tali o ni ibinujẹ? tali o ni ijà? tali o ni asọ̀? tali o ni ọgbẹ lainidi, tali o ni oju pipọn.
Awọn ti o duro pẹ nibi ọti-waini; awọn ti nlọ idan ọti-waini àdalu wò.
Iwọ máṣe wò ọti-waini pe o pọn, nigbati o ba fi àwọ rẹ̀ han ninu ago, ti a ngbe e mì, ti o ndùn.
Nikẹhin on a buniṣán bi ejò, a si bunijẹ bi paramọlẹ.
Oju rẹ yio wò awọn ajeji obinrin, aiya rẹ yio si sọ̀rọ ayidayida.
Nitõtọ, iwọ o dabi ẹniti o dubulẹ li arin okun, tabi ẹniti o dubulẹ lòke òpó-ọkọ̀.
Iwọ o si wipe, nwọn lù mi; kò dùn mi; nwọn lù mi, emi kò si mọ̀: nigbawo li emi o ji? emi o tun ma wá a kiri.