Owe 20:5-7

Owe 20:5-7 YBCV

Ìmọ ninu ọkàn enia dabi omi jijin; ṣugbọn amoye enia ni ifà a jade. Ọ̀pọlọpọ enia ni ima fọnrere, olukuluku ọrẹ ara rẹ̀: ṣugbọn olõtọ enia tani yio ri i. Olõtọ enia nrìn ninu iwa-titọ rẹ̀: ibukún si ni fun awọn ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀!