Owe 18:17-21

Owe 18:17-21 YBCV

Ẹnikini ninu ẹjọ rẹ̀ a dabi ẹnipe o jare, ṣugbọn ẹnikeji rẹ̀ a wá, a si hudi rẹ̀ silẹ. Keké mu ìja pari, a si làja lãrin awọn alagbara. Arakunrin ti a ṣẹ̀ si, o ṣoro jù ilu olodi lọ: ìja wọn si dabi ọpá idabu ãfin. Ọ̀rọ ẹnu enia ni yio mu inu rẹ̀ tutu: ibisi ẹnu rẹ̀ li a o si fi tù u ninu. Ikú ati ìye mbẹ ni ipa ahọn: awọn ẹniti o ba si nlò o yio jẹ ère rẹ̀.