Owe 15:26-33

Owe 15:26-33 YBCV

Ìro inu enia buburu, irira ni loju Oluwa; ṣugbọn mimọ́ ni ọ̀rọ didùn niwaju rẹ̀. Ẹniti o njẹ ère aiṣododo, o nyọ ile ara rẹ̀ lẹnu; ṣugbọn ẹniti o korira ẹ̀bun yio yè. Aiya olododo ṣe àṣaro lati dahùn; ṣugbọn ẹnu enia buburu ngufẹ ohun ibi jade. Oluwa jina si awọn enia-buburu; ṣugbọn o gbọ́ adura awọn olododo. Imọlẹ oju mu inu dùn; ihin rere si mu egungun sanra. Ẹniti o ba gbọ́ ibawi ìye, a joko lãrin awọn ọlọgbọ́n. Ẹniti o kọ̀ ẹkọ́, o gàn ọkàn ara rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o ba gbọ́ ibawi, o ni imoye. Ibẹ̀ru Oluwa li ẹkọ́ ọgbọ́n; ati ṣãju ọlá ni irẹlẹ.