Owe 15:26-29

Owe 15:26-29 YBCV

Ìro inu enia buburu, irira ni loju Oluwa; ṣugbọn mimọ́ ni ọ̀rọ didùn niwaju rẹ̀. Ẹniti o njẹ ère aiṣododo, o nyọ ile ara rẹ̀ lẹnu; ṣugbọn ẹniti o korira ẹ̀bun yio yè. Aiya olododo ṣe àṣaro lati dahùn; ṣugbọn ẹnu enia buburu ngufẹ ohun ibi jade. Oluwa jina si awọn enia-buburu; ṣugbọn o gbọ́ adura awọn olododo.