Owe 14:29-33

Owe 14:29-33 YBCV

Ẹniti o ba lọra ati binu, o ni ìmọ pupọ; ṣugbọn ẹniti o ba yara binu o gbe wère leke. Ọkàn ti o yè kõro ni ìye ara; ṣugbọn ilara ni ibajẹ egungun. Ẹniti o ba nni talaka lara, o gàn Ẹlẹda rẹ̀; ṣugbọn ẹniti o ṣãnu fun talaka o bu ọlá fun u. A pa enia buburu run ninu ìwa-buburu rẹ̀; ṣugbọn olododo ni ireti ninu ikú rẹ̀. Ọgbọ́n fi idi kalẹ li aiya ẹniti o moye; ṣugbọn a fi i hàn laiya awọn aṣiwère.