Owe 11:27-31

Owe 11:27-31 YBCV

Ẹniti o fi ara balẹ wá rere, a ri oju-rere: ṣugbọn ẹniti o nwá ibi kiri, o mbọ̀wá ba a. Ẹniti o ba gbẹkẹle ọrọ̀ rẹ̀ yio ṣubu: ṣugbọn olododo yio ma gbà bi ẹka igi. Ẹniti o ba yọ ile ara rẹ̀ li ẹnu yio jogun ofo: aṣiwere ni yio ma ṣe iranṣẹ fun ọlọgbọ́n aiya. Eso ododo ni igi ìye; ẹniti o ba si yi ọkàn enia pada, ọlọgbọ́n ni. Kiye si i a o san a fun olododo li aiye: melomelo li enia buburu ati ẹ̀lẹṣẹ.