Owe 10:17-32

Owe 10:17-32 YBCV

Ẹniti o ba pa ẹkọ́ mọ́, o wà ni ipa-ọ̀na ìye; ṣugbọn ẹniti o ba kọ̀ ibawi o ṣìna. Ẹniti o ba pa ikorira mọ́ li ète eke, ati ẹniti o ba ngba ọ̀rọ-ẹ̀hin, aṣiwere ni. Ninu ọ̀rọ pipọ, a kò le ifẹ ẹ̀ṣẹ kù: ṣugbọn ẹniti o fi ète mọ ète li o gbọ́n. Ahọn olõtọ dabi ãyo fadaka: aiya enia buburu kò ni iye lori. Ete olododo mbọ́ ọ̀pọlọpọ enia: ṣugbọn awọn aṣiwere yio kú li ailọgbọ́n. Ibukún Oluwa ni imu ni ilà, kì isi ifi lãla pẹlu rẹ̀. Bi ẹrín ni fun aṣiwere lati hu ìwa-ika: ṣugbọn ọlọgbọ́n li ẹni oye. Ibẹ̀ru enia buburu mbọwá ba a: ṣugbọn ifẹ olododo li a o fi fun u. Bi ìji ti ijà rekọja: bẹ̃li enia buburu kì yio si mọ: ṣugbọn olododo ni ipilẹ ainipẹkun. Bi ọti kikan si ehin, ati bi ẽfin si oju, bẹ̃li ọlẹ si ẹniti o rán a ni iṣẹ. Ibẹ̀ru Oluwa mu ọjọ gùn: ṣugbọn ọdun enia buburu li a o ṣẹ́ kuru. Abá olododo ayọ̀ ni yio jasi: ṣugbọn ireti enia buburu ni yio ṣegbe. Ọ̀na Oluwa jẹ́ ãbò fun ẹni iduroṣinṣin, ṣugbọn egbe ni fun awọn oniṣẹ-ẹ̀ṣẹ. A kì yio ṣi olododo ni ipo lai; ṣugbọn enia buburu kì yio gbe ilẹ̀-aiye. Ẹnu olõtọ mu ọgbọ́n jade; ṣugbọn ahọn arekereke li a o ke kuro. Ete olododo mọ̀ ohun itẹwọgba; ṣugbọn ẹnu enia buburu nsọ̀rọ arekereke.

Àwọn àwòrán ẹsẹ fún Owe 10:17-32

Owe 10:17-32 - Ẹniti o ba pa ẹkọ́ mọ́, o wà ni ipa-ọ̀na ìye; ṣugbọn ẹniti o ba kọ̀ ibawi o ṣìna.
Ẹniti o ba pa ikorira mọ́ li ète eke, ati ẹniti o ba ngba ọ̀rọ-ẹ̀hin, aṣiwere ni.
Ninu ọ̀rọ pipọ, a kò le ifẹ ẹ̀ṣẹ kù: ṣugbọn ẹniti o fi ète mọ ète li o gbọ́n.
Ahọn olõtọ dabi ãyo fadaka: aiya enia buburu kò ni iye lori.
Ete olododo mbọ́ ọ̀pọlọpọ enia: ṣugbọn awọn aṣiwere yio kú li ailọgbọ́n.
Ibukún Oluwa ni imu ni ilà, kì isi ifi lãla pẹlu rẹ̀.
Bi ẹrín ni fun aṣiwere lati hu ìwa-ika: ṣugbọn ọlọgbọ́n li ẹni oye.
Ibẹ̀ru enia buburu mbọwá ba a: ṣugbọn ifẹ olododo li a o fi fun u.
Bi ìji ti ijà rekọja: bẹ̃li enia buburu kì yio si mọ: ṣugbọn olododo ni ipilẹ ainipẹkun.
Bi ọti kikan si ehin, ati bi ẽfin si oju, bẹ̃li ọlẹ si ẹniti o rán a ni iṣẹ.
Ibẹ̀ru Oluwa mu ọjọ gùn: ṣugbọn ọdun enia buburu li a o ṣẹ́ kuru.
Abá olododo ayọ̀ ni yio jasi: ṣugbọn ireti enia buburu ni yio ṣegbe.
Ọ̀na Oluwa jẹ́ ãbò fun ẹni iduroṣinṣin, ṣugbọn egbe ni fun awọn oniṣẹ-ẹ̀ṣẹ.
A kì yio ṣi olododo ni ipo lai; ṣugbọn enia buburu kì yio gbe ilẹ̀-aiye.
Ẹnu olõtọ mu ọgbọ́n jade; ṣugbọn ahọn arekereke li a o ke kuro.
Ete olododo mọ̀ ohun itẹwọgba; ṣugbọn ẹnu enia buburu nsọ̀rọ arekereke.