Owe 1:29-33

Owe 1:29-33 YBCV

Nitori ti nwọn korira ìmọ, nwọn kò si yàn ibẹ̀ru Oluwa. Nwọn kò fẹ ìgbimọ mi: nwọn gàn gbogbo ibawi mi. Nitorina ni nwọn o ṣe ma jẹ ninu ère ìwa ara wọn, nwọn o si kún fun ìmọkimọ wọn. Nitoripe irọra awọn alaimọ̀kan ni yio pa wọn, ati alafia awọn aṣiwere ni yio pa wọn run. Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fetisi mi yio ma gbe lailewu, yio si farabalẹ kuro ninu ibẹ̀ru ibi.