Filp 2:1-7

Filp 2:1-7 YBCV

NITORINA bi itunu kan ba wà ninu Kristi, bi iṣipẹ ifẹ kan ba si wà, bi ìdapọ ti Ẹmí kan ba wà, bi ìyọ́nu-anu ati iṣeun ba wà, Ẹ mu ayọ̀ mi kún, ki ẹnyin ki o le jẹ oninu kanna, ki imọ̀ nyin ki o ṣọkan, ki ẹ si ni ọkàn kan. Ẹ máṣe fi ìja tabi ogo asan ṣe ohunkohun: ṣugbọn ni irẹlẹ ọkàn ki olukuluku ro awọn ẹlomiran si ẹniti o san ju on tikararẹ̀ lọ. Ki olukuluku nyin ki o máṣe wo ohun tirẹ̀, ṣugbọn olukuluku ohun ti ẹlomiran. Ẹ ni ero yi ninu nyin, eyi ti o ti wà pẹlu ninu Kristi Jesu: Ẹniti o tilẹ jẹ aworan Ọlọrun, ti kò ka a si iwọra lati ba Ọlọrun dọgba: Ṣugbọn o bọ́ ogo rẹ̀ silẹ, o si mu awọ̀ iranṣẹ, a si ṣe e ni awòran enia.