Num 6:8-27

Num 6:8-27 YBCV

Ni gbogbo ọjọ́ ìyasapakan rẹ̀, mimọ́ li on fun OLUWA. Bi enia kan ba si kú lojiji lẹba ọdọ rẹ̀, ti o ba si bà ori ìyasapakan rẹ̀ jẹ́; nigbana ni ki o fá ori rẹ̀ li ọjọ́ ìwẹnumọ́ rẹ̀, ni ijọ́ keje ni ki o fá a. Ati ni ijọ́ kẹjọ ki o mú àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji tọ̀ alufa wá, si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ: Ki alufa ki o si ru ọkan li ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji li ẹbọ sisun, ki o si ṣètutu fun u, nitoriti o ṣẹ̀ nipa okú, ki o si yà ori rẹ̀ simimọ́ li ọjọ́ na. Ki o si yà ọjọ́ ìyasapakan rẹ̀ simimọ́ si OLUWA, ki o si mú akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan wá, fun ẹbọ ẹbi: ṣugbọn ọjọ́ ti o ti ṣaju yio di asan, nitoripe ìyasapakan rẹ̀ bàjẹ́. Eyi si li ofin ti Nasiri, nigbati ọjọ́ ìyasapakan rẹ̀ ba pé: ki a si mú u wá si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ: On o si mú ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ wá fun OLUWA, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan alailabùkun fun ẹbọ sisun, ati abo ọdọ-agutan kan ọlọdún kan alailabùkun fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati àgbo kan alailabùkun fun ẹbọ alafia. Ati agbọ̀n àkara alaiwu kan, àkara adidùn iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, ati àkara fẹlẹfẹlẹ alaiwu ti a ta oróro si, ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn. Ki alufa ki o mú wọn wá siwaju OLUWA, ki o si ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ati ẹbọ sisun rẹ̀: Ki o si ru àgbo na li ẹbọ alafia si OLUWA, pẹlu agbọ̀n àkara alaiwu: ki alufa pẹlu ki o si ru ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀. Ki Nasiri na ki o fá ori ìyasapakan rẹ̀ li ẹnu-ọ̀na agọ́ àjọ, ki o si mú irun ori ìyasapakan rẹ̀ ki o si fi i sinu iná ti mbẹ labẹ ẹbọ alafia na. Ki alufa ki o si mú apá bibọ̀ àgbo na, ati àkara adidùn kan alaiwu kuro ninu agbọ̀n na, ati àkara fẹlẹfẹlẹ kan alaiwu, ki o si fi wọn lé ọwọ́ Nasiri na, lẹhin ìgba ti a fá irun ori ìyasapakan rẹ̀ tán: Ki alufa ki o si fì wọn li ẹbọ fifì niwaju OLUWA: mimọ́ li eyi fun alufa na, pẹlu àiya fifì, ati itan agbesọsoke: lẹhin na Nasiri na le ma mu ọti-waini. Eyi li ofin ti Nasiri ti o ṣe ileri, ati ti ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ si OLUWA fun ìyasapakan rẹ̀ li àika eyiti ọwọ́ on le tẹ̀: gẹgẹ bi ileri ti o ṣe, bẹ̃ni ki o ṣe nipa ofin ìyasapakan rẹ̀. OLUWA si sọ fun Mose pe, Sọ fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, Bayi li ẹnyin o ma sure fun awọn ọmọ Israeli; ki ẹ ma wi fun wọn pe, Ki OLUWA ki o busi i fun ọ, ki o si pa ọ mọ́: Ki OLUWA ki o mu oju rẹ̀ mọlẹ si ọ lara, ki o si ṣãnu fun ọ: Ki OLUWA ki o ma bojuwò ọ, ki o si ma fun ọ ni alafia. Bayi ni nwọn o fi orukọ mi sara awọn ọmọ Israeli; emi o si busi i fun wọn.