Num 6:22-26

Num 6:22-26 YBCV

OLUWA si sọ fun Mose pe, Sọ fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, Bayi li ẹnyin o ma sure fun awọn ọmọ Israeli; ki ẹ ma wi fun wọn pe, Ki OLUWA ki o busi i fun ọ, ki o si pa ọ mọ́: Ki OLUWA ki o mu oju rẹ̀ mọlẹ si ọ lara, ki o si ṣãnu fun ọ: Ki OLUWA ki o ma bojuwò ọ, ki o si ma fun ọ ni alafia.