OLUWA si sọ fun Mose ati Aaroni pe,
Kà iye awọn ọmọ Kohati kuro ninu awọn ọmọ Lefi, nipa idile wọn, ile baba wọn,
Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, ani titi di ẹni ãdọta ọdún, gbogbo ẹniti o wọ̀ inu iṣẹ-ìsin, lati ṣe iṣẹ ninu agọ́ ajọ.
Eyi ni yio ṣe iṣẹ-ìsin awọn ọmọ Kohati ninu agọ́ ajọ, niti ohun mimọ́ julọ wọnni:
Nigbati ibudó ba si ṣí siwaju, Aaroni o wá, ati awọn ọmọ rẹ̀, nwọn o si bọ́ aṣọ-ikele rẹ̀ silẹ, nwọn o si fi i bò apoti ẹrí;
Nwọn o fi awọ seali bò o, nwọn o si nà aṣọ kìki alaró bò o, nwọn o si tẹ̀ ọpá nì bọ̀ ọ.
Ati lori tabili àkara ifihàn nì, ki nwọn ki o nà aṣọ alaró kan si, ki nwọn ki o si fi awopọkọ sori rẹ̀, ati ṣibi ati awokòto, ati ìgo ohun didà: ati àkara ìgbagbogbo nì ki o wà lori rẹ̀:
Ki nwọn ki o si nà aṣọ ododó bò wọn, ki nwọn ki o si fi awọ seali bò o, ki nwọn ki o si tẹ̀ ọpá rẹ̀ bọ̀ ọ.
Ki nwọn ki o si mú aṣọ alaró kan, ki nwọn ki o si fi bò ọpá-fitila nì, ati fitila rẹ̀, ati alumagaji rẹ̀, ati awo alumagaji rẹ̀, ati gbogbo ohunèlo oróro rẹ̀, eyiti nwọn fi nṣe iṣẹ rẹ̀.
Ki nwọn ki o si fi on ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀ sinu awọ seali, ki nwọn ki o si gbé e lé ori igi.
Ati lori pẹpẹ wurà ni ki nwọn ki o nà aṣọ alaró kan si, nwọn o si fi awọ seali bò o, nwọn o si tẹ̀ ọpá rẹ̀ bọ̀ ọ.
Ki nwọn ki o si kó gbogbo ohunèlo ìsin, ti nwọn fi nṣe iṣẹ-ìsin ninu ibi-mimọ́, ki nwọn ki o si fi wọn sinu aṣọ alaró kan, ki nwọn ki o si fi awọ seali bò wọn, ki nwon ki o si fi wọn kà ori igi.
Ki nwọn ki o si kó ẽru kuro lori pẹpẹ, ki nwọn ki o si nà aṣọ elesè-aluko kan bò o.
Ki nwọn ki o si fi gbogbo ohun-èlo rẹ̀ ti nwọn fi ṣe iṣẹ-ìsin rẹ̀ sori rẹ̀, awo iná, ati kọkọrọ ẹran, ati ọkọ́-ẽru, ati awokòto, ati gbogbo ohun-èlo pẹpẹ na; ki nwọn ki o si nà awọ seali sori rẹ̀, ki nwọn ki o si tẹ ọpá rẹ̀ bọ̀ ọ.
Nigbati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ ba pari ati bò ibi-mimọ́ na tán, ati gbogbo ohun-èlo ibi-mimọ́ na, nigbati ibudó yio ba ṣí siwaju; lẹhin eyinì, li awọn ọmọ Kohati yio wá lati gbé e: ṣugbọn nwọn kò gbọdọ fọwọkàn ohun mimọ́ kan, ki nwọn ki o má ba kú. Wọnyi li ẹrù awọn ọmọ Kohati ninu agọ́ ajọ.
Ohun itọju Eleasari ọmọ Aaroni alufa si ni oróro fitila, ati turari didùn, ati ẹbọ ohunjijẹ ìgbagbogbo, ati oróro itasori, ati itọju agọ́ na gbogbo, ati ti ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀, ninu ibi-mimọ́ nì, ati ohun-èlo rẹ̀ na.
OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe,
Ẹ máṣe ke ẹ̀ya idile awọn ọmọ Kohati kuro lãrin awọn ọmọ Lefi:
Ṣugbọn bayi ni ki ẹ ṣe fun wọn, ki nwọn ki o le yè, ki nwọn ki o má ba kú, nigbati nwọn ba sunmọ ohun mimọ́ julọ: ki Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ wọnú ilé, ki nwọn si yàn wọn olukuluku si iṣẹ rẹ̀ ati si ẹrù rẹ̀;
Ṣugbọn nwọn kò gbọdọ wọle lọ lati wò ohun mimọ́ ni iṣẹju kan, ki nwọn ki o má ba kú.
OLUWA si sọ fun Mose pe,
Kà iye awọn ọmọ Gerṣoni pẹlu, gẹgẹ bi ile baba wọn, nipa idile wọn;
Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ titi di ẹni ãdọta ọdún ni ki o kaye wọn; gbogbo awọn ti o wọnu-ile lọ lati ṣe iṣẹ-ìsin, lati ṣe iṣẹ ninu agọ́ ajọ.
Eyi ni iṣẹ-ìsin idile awọn ọmọ Gerṣoni, lati sìn ati lati rù ẹrù:
Awọn ni yio si ma rù aṣọ-ikele agọ́, ati agọ́ ajọ, ibori rẹ̀, ati ibori awọ seali ti mbẹ lori rẹ̀, ati aṣọ-tita fun ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ;
Ati aṣọ-isorọ̀ ti agbalá, ati aṣọ-tita fun ẹnu-ọ̀na agbalá, ti mbẹ lẹba agọ́ ati lẹba pẹpẹ yiká, ati okùn wọn, ati gbogbo ohun-èlo iṣẹ-ìsin wọn, ati ohun gbogbo ti a ṣe fun wọn; bẹ̃ni nwọn o ma sìn.
Nipa aṣẹ Aaroni ati ti awọn ọmọ rẹ̀ ni ki gbogbo iṣẹ-ìsin awọn ọmọ Gerṣoni jẹ́, ni gbogbo ẹrù wọn, ati ni gbogbo iṣẹ-ìsin wọn: ki ẹnyin si yàn wọn si itọju gbogbo ẹrù wọn.
Eyi ni iṣẹ-ìsin idile awọn ọmọ Gerṣoni ninu agọ́ ajọ: ki itọju wọn ki o si wà li ọwọ́ Itamari ọmọ Aaroni alufa.
Ati awọn ọmọ Merari, ki iwọ ki o kà wọn gẹgẹ bi idile wọn, nipa ile baba wọn;
Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ ani titi di ẹni ãdọta ọdún ni ki iwọ ki o kà wọn, gbogbo ẹniti o wọ̀ inu iṣẹ-ìsin na lati ṣe iṣẹ ninu agọ́ ajọ́.
Eyi si ni itọju ẹrù wọn, gẹgẹ bi gbogbo iṣẹ-ìsin wọn ninu agọ́ ajo; awọn apáko agọ́, ati ọpá-idabu rẹ̀, ati opó rẹ̀, ati ìhò-ìtẹbọ rẹ̀,
Ati opó agbalá yiká, ati ihò-ìtẹbọ wọn, ati ẽkàn wọn, ati okùn wọn, pẹlu ohun-èlo wọn gbogbo, ati pẹlu ohun-ìsin wọn gbogbo: li orukọ li orukọ ni ki ẹnyin ki o kà ohun-èlo ti iṣe itọju ẹrù wọn.