Balaki si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, bá mi lọ si ibomiran, lati ibiti iwọ o le ri wọn; kìki apakan wọn ni iwọ o ri, iwọ ki yio si ri gbogbo wọn tán; ki o si fi wọn bú fun mi lati ibẹ̀ lọ.
O si mú u wá si igbẹ Sofimu sori òke Pisga, o si mọ pẹpẹ meje, o si fi akọmalu kan ati àgbo kan rubọ lori pẹpẹ kọkan.
On si wi fun Balaki pe, Duro nihin tì ẹbọ sisun rẹ, emi o si lọ ipade OLUWA lọhùn yi.
OLUWA si pade Balaamu, o si fi ọ̀rọ si i li ẹnu, wipe, Tun pada tọ̀ Balaki lọ, ki o si wi bayi.
O si tọ̀ ọ wá, kiyesi i, o duro tì ẹbọ sisun rẹ̀, ati awọn ijoye Moabu pẹlu rẹ̀. Balaki si bi i pe, Kini OLUWA sọ?
O si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Dide, Balaki, ki o si gbọ́; ki o si fetisi mi, iwọ ọmọ Sipporu:
Ọlọrun ki iṣe enia ti yio fi ṣeké; bẹ̃ni ki iṣe ọmọ enia ti yio fi ronupiwada: a ma wi, ki o má si ṣe bi? tabi a ma sọ̀rọ ki o má mu u ṣẹ?
Kiyesi i, emi gbà aṣẹ ati sure: on si ti sure, emi kò si le yì i.
On kò ri ẹ̀ṣẹ ninu Jakobu, bẹ̃ni kò ri ibi ninu Israeli: OLUWA Ọlọrun rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ihó-ayọ ọba si mbẹ ninu wọn.
Ọlọrun mú wọn lati Egipti jade wá; o ní agbara bi ti agbanrere.
Nitõtọ kò sí ìfaiya si Jakobu, bẹ̃ni kò sí afọṣẹ si Israeli: nisisiyi li a o ma wi niti Jakobu ati niti Israeli, Ohun ti Ọlọrun ṣe!
Kiyesi i, awọn enia na yio dide bi abokiniun, yio si gbé ara rẹ̀ soke bi kiniun: on ki yio dubulẹ titi yio fi jẹ ohun ọdẹ, titi yio si fi mu ninu ẹ̀jẹ ohun pipa.
Balaki si wi fun Balaamu pe, Kuku má fi wọn bú, bẹ̃ni ki o máṣe sure fun wọn rára.
Ṣugbọn Balaamu dahún, o si wi fun Balaki pe, Emi kò ha ti wi fun ọ pe, Gbogbo eyiti OLUWA ba sọ, on ni emi o ṣe?
Balaki si wi fun Balaamu pe, Wá, emi bẹ̀ ọ, emi o mú ọ lọ si ibomiran; bọya yio wù Ọlọrun ki iwọ ki o fi wọn bú fun mi lati ibẹ̀ lọ.
Balaki si mú Balaamu wá sori òke Peoru, ti o kọjusi aginjù.
Balaamu si wi fun Balaki pe, Mọ pẹpẹ meje fun mi nihin, ki o si pèse akọmalu meje ati àgbo meje fun mi nihin.
Balaki si ṣe bi Balaamu ti wi, o si fi akọmalu kan ati àgbo kan rubọ lori pẹpẹ kọkan.