Nwọn si rìn lati òke Hori lọ li ọ̀na Okun Pupa, lati yi ilẹ Edomu ká: sũru si tán awọn enia na pupọ̀pupọ nitori ọ̀na na. Awọn enia na si bá Ọlọrun, ati Mose sọ̀ pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi mú wa gòke lati Egipti jade wá lati kú li aginjù? nitoripe àkara kò sí, bẹ̃ni kò sí omi; onjẹ futẹfutẹ yi si sú ọkàn wa. OLUWA si rán ejò amubina si awọn enia na, nwọn si bù awọn enia na ṣan; ọ̀pọlọpọ ninu Israeli si kú. Nitorina li awọn enia na ṣe tọ̀ Mose wá, nwọn si wipe, Awa ti ṣẹ̀, nitoriti awa ti bá OLUWA ati iwọ sọ̀; gbadura si OLUWA ki o mú ejò wọnyi kuro lọdọ wa. Mose si gbadura fun awọn enia na. OLUWA si wi fun Mose pe, Rọ ejò amubina kan, ki o si fi i sori ọpá-gigùn kan: yio si ṣe, olukuluku ẹniti ejò ba bùṣan, nigbati o ba wò o, yio yè.
Kà Num 21
Feti si Num 21
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Num 21:4-8
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò