Ki alufa ki o si ṣètutu fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, a o si darijì wọn; nitoripe aimọ̀ ni, nwọn si ti mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA, ati ẹbọ ẹ̀ṣẹ wọn niwaju OLUWA, nitori aimọ̀ wọn: A o si darijì gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, ati alejò ti iṣe atipo lọdọ wọn; nitoripe gbogbo enia wà li aimọ̀. Bi ọkàn kan ba si fi aimọ̀ ṣẹ̀, nigbana ni ki o mú abo-ewurẹ ọlọdún kan wá, fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ. Ki alufa ki o ṣètutu fun ọkàn na ti o ṣẹ̀, nigbati o ba ṣẹ̀ li aimọ̀ niwaju OLUWA, lati ṣètutu fun u; a o si darijì i. Ofin kan ni ki ẹnyin ki o ní fun ẹniti o ṣẹ̀ ni aimọ̀, ati fun ẹniti a bi ninu awọn ọmọ Israeli, ati fun alejò ti nṣe atipo ninu wọn. Ṣugbọn ọkàn na ti o ba fi ikugbu ṣe ohun kan, iba ṣe ibilẹ tabi alejò, o sọ̀rọbuburu si OLUWA; ọkàn na li a o si ke kuro ninu awọn enia rẹ̀. Nitoriti o gàn ọ̀rọ OLUWA, o si ru ofin rẹ̀; ọkàn na li a o ke kuro patapata, ẹ̀ṣẹ rẹ̀ yio wà lori rẹ̀. Nigbati awọn ọmọ Israeli wà li aginjù, nwọn ri ọkunrin kan ti nṣẹ́ igi li ọjọ́-isimi. Awọn ti o ri i ti nṣẹ́ igi mú u tọ̀ Mose ati Aaroni wá, ati gbogbo ijọ.
Kà Num 15
Feti si Num 15
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Num 15:25-33
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò