Num 14:20-23

Num 14:20-23 YBCV

OLUWA si wipe, Emi ti darijì gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ: Ṣugbọn nitõtọ, bi mo ti wà, gbogbo aiye yio si kún fun ogo OLUWA; Nitori gbogbo awọn enia wọnyi ti o ti ri ogo mi, ati iṣẹ-àmi mi, ti mo ti ṣe ni Egipti ati li aginjù, ti nwọn si dan mi wò nigba mẹwa yi, ti nwọn kò si fetisi ohùn mi; Nitõtọ nwọn ki yio ri ilẹ na ti mo ti fi bura fun awọn baba wọn, bẹ̃ni ọkan ninu awọn ti o gàn mi ki yio ri i