Num 10:11-13

Num 10:11-13 YBCV

O si ṣe li ogun ọjọ́ oṣù keji, li ọdún keji, ni awọsanma ká soke kuro lori agọ́ ẹrí. Awọn ọmọ Israeli si dide ìrin wọn lati ijù Sinai; awọsanma na si duro ni ijù Parani. Nwọn si bẹ̀rẹsi iṣí gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA nipa ọwọ́ Mose.