Neh 4:16-17

Neh 4:16-17 YBCV

O si ṣe, lati ọjọ na wá, idaji awọn ọmọkunrin mi ṣe iṣẹ na, idaji keji di ọ̀kọ, apata, ati ọrun, ati ihamọra mu; awọn olori si duro lẹhin gbogbo ile Juda. Awọn ti nmọ odi, ati awọn ti nrù ẹrù ati awọn ti o si ndi ẹrù, olukuluku wọn nfi ọwọ rẹ̀ kan ṣe iṣẹ, nwọn si fi ọwọ keji di ohun ìja mu.