Neh 4:15-18

Neh 4:15-18 YBCV

O si ṣe, nigbati awọn ọta wa gbọ́ pe, o di mimọ̀ fun wa, Ọlọrun ti sọ ìmọ wọn di asan, gbogbo wa si padà si odi na, olukuluku si iṣẹ rẹ̀. O si ṣe, lati ọjọ na wá, idaji awọn ọmọkunrin mi ṣe iṣẹ na, idaji keji di ọ̀kọ, apata, ati ọrun, ati ihamọra mu; awọn olori si duro lẹhin gbogbo ile Juda. Awọn ti nmọ odi, ati awọn ti nrù ẹrù ati awọn ti o si ndi ẹrù, olukuluku wọn nfi ọwọ rẹ̀ kan ṣe iṣẹ, nwọn si fi ọwọ keji di ohun ìja mu. Olukuluku awọn ọmọ kọ́ idà rẹ̀ li ẹgbẹ rẹ̀, bẹni nwọn si mọ odi. Ẹniti nfọn ipè wà li eti ọdọ mi.