Neh 13:8-11

Neh 13:8-11 YBCV

O si bà mi ninu jẹ gidigidi, nitorina mo da gbogbo ohun èlo Tobiah jade kuro ninu iyẹwu na. Nigbana ni mo paṣẹ, nwọn si wẹ̀ iyẹwu na mọ: si ibẹ ni mo si tun mu ohun èlo ile Ọlọrun wá, pẹlu ẹbọ ohun jijẹ ati turari. Mo si mọ̀ pe, a kò ti fi ipin awọn ọmọ Lefi fun wọn; awọn ọmọ Lefi ati awọn akọrin, ti nṣe iṣẹ, si ti salọ olukuluku si oko rẹ̀. Nigbana ni mo si ba awọn ijoye jà, mo si wipe, Ẽṣe ti a fi kọ̀ ile Ọlọrun silẹ? Mo si ko wọn jọ, mo si fi wọn si ipò wọn.