Neh 13:10-12

Neh 13:10-12 YBCV

Mo si mọ̀ pe, a kò ti fi ipin awọn ọmọ Lefi fun wọn; awọn ọmọ Lefi ati awọn akọrin, ti nṣe iṣẹ, si ti salọ olukuluku si oko rẹ̀. Nigbana ni mo si ba awọn ijoye jà, mo si wipe, Ẽṣe ti a fi kọ̀ ile Ọlọrun silẹ? Mo si ko wọn jọ, mo si fi wọn si ipò wọn. Nigbana ni gbogbo Juda mu idamẹwa ọka ati ọti-waini titun ati ororo wá si ile iṣura.