Neh 1:6-9

Neh 1:6-9 YBCV

Tẹ́ eti rẹ silẹ̀ nisisiyi, ki o si ṣi oju rẹ, ki iwọ ba le gbọ́ adura iranṣẹ rẹ, ti mo ngbà niwaju rẹ nisisiyi, tọsan toru fun awọn ọmọ Israeli iranṣẹ rẹ, ti mo si jẹwọ ẹ̀ṣẹ awọn ọmọ Israeli ti a ti ṣẹ̀ si ọ: ati emi ati ile baba mi ti ṣẹ̀. Awa ti huwa ibàjẹ si ọ, awa kò si pa ofin ati ilana ati idajọ mọ, ti iwọ pa li aṣẹ fun Mose iranṣẹ rẹ. Emi bẹ̀ ọ, ranti ọ̀rọ ti iwọ pa laṣẹ fun Mose iranṣẹ rẹ, wipe, Bi ẹnyin ba ṣẹ̀, emi o tú nyin kakiri sãrin awọn orilẹ-ède: Ṣugbọn bi ẹnyin ba yipada si mi, ti ẹ si pa ofin mi mọ, ti ẹ si ṣe wọn, bi o tilẹ ṣepe ẹnyin ti a ti tì jade wà ni ipẹkun ọrun, emi o ko wọn jọ lati ibẹ wá, emi o si mu wọn wá si ibi ti mo ti yàn lati fi orukọ mi si.