Nah 3:8-19

Nah 3:8-19 YBCV

Iwọ ha sàn jù No-ammoni, eyiti o wà lãrin odò ti omi yika kiri, ti agbara rẹ̀ jẹ okun, ti odi rẹ̀ si ti inu okun jade wá? Etiopia ati Egipti li agbara rẹ̀, kò si li opin; Puti ati Lubimu li awọn olùranlọwọ rẹ. Sibẹ̀sibẹ̀ a kó o lọ, o lọ si oko-ẹrú: awọn ọmọ wẹ́wẹ rẹ̀ li a fi ṣánlẹ̀ pẹlu li ori ita gbogbo; nwọn si di ibò nitori awọn ọlọla rẹ̀ ọkunrin, gbogbo awọn ọlọla rẹ̀ li a si fi ẹwọ̀n dì. Iwọ pẹlu o si yó ọti; a o si fi ọ pamọ, iwọ pẹlu o si ma ṣe afẹri ãbò nitori ti ọta na. Gbogbo ile-iṣọ agbara rẹ yio dabi igi ọpọ̀tọ pẹlu akọpọn ọpọ̀tọ: bi a ba gbọ̀n wọn, nwọn o si bọ si ẹnu ọjẹun. Kiye si i, obinrin li awọn enia rẹ lãrin rẹ: oju ibodè ilẹ rẹ li a o ṣi silẹ gbaguda fun awọn ọta rẹ: iná yio jo ikere rẹ. Iwọ pọn omi de ihamọ, mu ile iṣọ rẹ le: wọ̀ inu amọ̀, ki o si tẹ̀ erupẹ̀, ki o si ṣe ibiti a nsun okuta-amọ̀ ki o le. Nibẹ̀ ni iná yio jo ọ run; idà yio ké ọ kuro, yio si jẹ ọ bi kòkoro: sọ ara rẹ di pupọ̀ bi kòkoro, si sọ ara rẹ di pupọ̀ bi ẽṣu. Iwọ ti sọ awọn oniṣòwo rẹ di pupọ̀ jù iràwọ oju ọrun lọ: kokòro nà ara rẹ̀, o si fò lọ. Awọn alade rẹ dabi eṣú, awọn ọgagun rẹ si dabi ẹlẹngà nla, eyiti ndó sinu ọgbà la ọjọ otutù, ṣugbọn nigbati õrùn là, nwọn sa lọ, a kò si mọ̀ ibiti wọn gbe wà. Awọn olùṣọ agùtan rẹ ntõgbe, Iwọ ọba Assiria: awọn ọlọla rẹ yio ma gbe inu ekuru: awọn enia rẹ si tuka lori oke-nla, ẹnikan kò si kó wọn jọ. Kò si ipajumọ fun ifarapa rẹ; ọgbẹ rẹ kún fun irora, gbogbo ẹniti o gbọ́ ihin rẹ yio pàtẹwọ le ọ lori, nitori li ori tani ìwa-buburu rẹ kò ti kọja nigbagbogbo?