O si dide ti ibẹ̀ kuro, o si lọ si àgbegbe Tire on Sidoni, o si wọ̀ inu ile kan, ko si fẹ ki ẹnikẹni ki o mọ̀: ṣugbọn on kò le fi ara pamọ́. Nitori obinrin kan, ẹniti ọmọbinrin rẹ̀ kekere li ẹmi aimọ́ gburo rẹ̀, o wá, o si wolẹ lẹba ẹsẹ rẹ̀: Hellene si li obinrin na, Sirofenikia ni orilẹ-ède rẹ̀; o si bẹ̀ ẹ ki on iba lé ẹmi èṣu na jade lara ọmọbinrin rẹ̀. Ṣugbọn Jesu wi fun u pe, Jẹ ki a kọ́ fi onjẹ tẹ awọn ọmọ lọrun na: nitoriti ko tọ́ lati mu onjẹ awọn ọmọ, ki a si fi i fun ajá. O si dahùn o si wi fun u pe, Bẹni Oluwa: ṣugbọn awọn ajá pãpã a ma jẹ ẹrún awọn ọmọ labẹ tabili. O si wi fun u pe, Nitori ọ̀rọ yi, mã lọ; ẹmi ẹ̀ṣu na ti jade kuro lara ọmọbinrin rẹ. Nigbati o si pada wá si ile rẹ̀, o ri pe ẹmi èṣu na ti jade, ọmọbinrin rẹ̀ si sùn lori akete.
Kà Mak 7
Feti si Mak 7
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Mak 7:24-30
9 Days
New York Times bestselling author and renowned pastor, Timothy Keller shares a series of episodes from the life of Jesus as told in the book of Mark. Taking a closer look at these stories, he brings new insights on the relationship between our lives and the life of the son of God, leading up to Easter. JESUS THE KING is now a book and study guide for small groups, available wherever books are sold.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò