Ẹniti o ba li etí lati fi gbọ́, ki o gbọ́. Nigbati o si ti ọdọ awọn enia kuro wọ̀ inu ile, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si bi i lẽre niti owe na. O si wi fun wọn pe, Ẹnyin pẹlu wà li aimoye tobẹ̃? ẹnyin ko kuku kiyesi pe, ohunkohun ti o wọ̀ inu enia lati ode lọ, ko le sọni di alaimọ́; Nitoriti ko lọ sinu ọkàn rẹ̀, ṣugbọn sinu ara, a si yà a jade, a si gbá gbogbo onjẹ danù? O si wipe, Eyi ti o ti inu enia jade, eyini ni isọ enia di alaimọ́. Nitori lati inu, lati inu ọkàn enia ni iro buburu ti ijade wá, panṣaga, àgbere, ipania, Olè, ojukòkoro, iwa buburu, itanjẹ, wọ̀bia, oju buburu, isọrọ-odi, igberaga, iwère: Lati inu wá ni gbogbo nkan buburu wọnyi ti ijade, nwọn a si sọ enia di alaimọ́.
Kà Mak 7
Feti si Mak 7
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Mak 7:16-23
9 Days
New York Times bestselling author and renowned pastor, Timothy Keller shares a series of episodes from the life of Jesus as told in the book of Mark. Taking a closer look at these stories, he brings new insights on the relationship between our lives and the life of the son of God, leading up to Easter. JESUS THE KING is now a book and study guide for small groups, available wherever books are sold.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò