Nigbati o si di ọjọ isimi, o bẹ̀rẹ si ikọni ninu sinagogu; ẹnu si yà awọn enia pipọ ti o gbọ́, nwọn wipe, Nibo li ọkunrin yi gbé ti ri nkan wọnyi? irú ọgbọ́n kili eyi ti a fifun u, ti irú iṣẹ agbara bayi nti ọwọ́ rẹ̀ ṣe? Gbẹnagbẹna na kọ yi, ọmọ Maria, arakunrin Jakọbu, ati Jose, ati ti Juda, ati Simoni? awọn arabinrin rẹ̀ kò ha si wà nihinyi lọdọ wa? Nwọn si kọsẹ̀ lara rẹ̀. Ṣugbọn Jesu wi fun wọn pe, Ko si woli ti o wà laili ọlá, bikoṣe ni ilu on tikararẹ̀, ati larin awọn ibatan rẹ̀, ati ninu ile rẹ̀.
Kà Mak 6
Feti si Mak 6
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Mak 6:2-4
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò