O si bi i lẽre pe, Orukọ rẹ? O si dahùn, wipe, Legioni li orukọ mi: nitori awa pọ̀. O si bẹ̀ ẹ gidigidi pe, ki o máṣe rán wọn jade kuro ni ilẹ na. Agbo ọ̀pọ ẹlẹdẹ kan si wà nibẹ ti njẹ lẹba oke. Gbogbo awọn ẹmi èṣu bẹ̀ ẹ wipe, Rán wa lọ sinu awọn ẹlẹdẹ, ki awa ki o le wọ̀ inu wọn lọ. Lọgan Jesu si jọwọ wọn. Awọn ẹmi aimọ́ si jade, nwọn si wọ̀ inu awọn ẹlẹdẹ lọ: agbo ẹlẹdẹ si tupũ nwọn si sure ni gẹrẹgẹrẹ lọ sinu okun (nwọn si to ìwọn ẹgbã;) nwọn si kú sinu okun.
Kà Mak 5
Feti si Mak 5
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Mak 5:9-13
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò