Mak 5:27-30

Mak 5:27-30 YBCV

Nigbati o gburo Jesu, o wá sẹhin rẹ̀ larin ọ̀pọ enia, o fọwọ́kàn aṣọ rẹ̀. Nitori o wipe, Bi mo ba sá le fi ọwọ́ mi kàn aṣọ rẹ̀, ara mi yio da. Lọgan ni isun ẹ̀jẹ rẹ̀ si ti gbẹ; on si mọ̀ lara rẹ̀ pe, a mu on larada ninu arun na. Lọgan Jesu si ti mọ̀ ninu ara rẹ̀ pe, aṣẹ ti ara on jade, o yipada larin ọpọ enia, o si wipe, Tali o fi ọwọ́ kàn mi li aṣọ?

Àwọn fídíò fún Mak 5:27-30