Mak 4:26-29

Mak 4:26-29 YBCV

O si wipe, Bẹ̃ sá ni ijọba Ọlọrun, o dabi ẹnipe ki ọkunrin kan funrugbin sori ilẹ; Ki o si sùn, ki o si dide li oru ati li ọsán, ki irugbin na ki o si sọ jade ki o si dàgba, on kò si mọ̀ bi o ti ri. Nitori ilẹ a ma so eso jade fun ara rẹ̀; ekini ẽhù, lẹhinna ipẹ́, lẹhinna ikunmọ ọkà ninu ipẹ́. Ṣugbọn nigbati eso ba pọ́n tan, lojukanna on a tẹ̀ doje bọ inu rẹ̀ nitori igba ikorè de.

Àwọn fídíò fún Mak 4:26-29