Mak 4:21-34

Mak 4:21-34 YBCV

O si wi fun wọn pe, A ha gbé fitilà wá lati fi sabẹ òṣuwọn, tabi sabẹ akete, ki a ma si ṣe gbé e kà ori ọpá fitilà? Nitori kò si ohun ti o pamọ́ bikoṣe ki a le fi i hàn; bẹ̃ni kò si ohun ti o wà ni ikọkọ, bikoṣepe ki o le yọ si gbangba. Bi ẹnikẹni ba li etí lati fi gbọ́, ki o gbọ́. O si wi fun wọn pe, Ẹ mã kiyesi ohun ti ẹnyin ngbọ́: òṣuwọn ti ẹnyin ba fi wọ̀n, on li a o fi wọ̀n fun nyin: a o si fi kún u fun nyin. Nitori ẹniti o ba ni, on li a o fifun: ati ẹniti kò ba si ni, lọwọ rẹ̀ li a o si gbà eyi na ti o ni. O si wipe, Bẹ̃ sá ni ijọba Ọlọrun, o dabi ẹnipe ki ọkunrin kan funrugbin sori ilẹ; Ki o si sùn, ki o si dide li oru ati li ọsán, ki irugbin na ki o si sọ jade ki o si dàgba, on kò si mọ̀ bi o ti ri. Nitori ilẹ a ma so eso jade fun ara rẹ̀; ekini ẽhù, lẹhinna ipẹ́, lẹhinna ikunmọ ọkà ninu ipẹ́. Ṣugbọn nigbati eso ba pọ́n tan, lojukanna on a tẹ̀ doje bọ inu rẹ̀ nitori igba ikorè de. O si wipe, Kili a o fi ijọba Ọlọrun we? tabi kili a ba fi ṣe akawe rẹ̀? O dabi wóro irugbin mustardi, eyiti, nigbati a gbin i si ilẹ, bi o tilẹ ṣe pe o kére jù gbogbo irugbin ti o wa ni ilẹ lọ, Sibẹ nigbati a gbin i o dàgba soke, o si di titobi jù gbogbo ewebẹ lọ, o si pa ẹká nla; tobẹ ti awọn ẹiyẹ oju ọrun le ma gbe abẹ ojiji rẹ̀. Irù ọ̀pọ owe bẹ̃ li o fi mba wọn nsọ̀rọ, niwọn bi nwọn ti le gbà a si. Ṣugbọn on kì iba wọn sọrọ laìsi owe: nigbati o ba si kù awọn nikan, on a si sọ idi ohun gbogbo fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.

Àwọn fídíò fún Mak 4:21-34