Mak 4:14-20

Mak 4:14-20 YBCV

Afunrugbin funrugbin ọ̀rọ na. Awọn wọnyi si ni ti ẹba ọ̀na, nibiti a funrugbin ọ̀rọ na; nigbati nwọn si ti gbọ́, lojukanna Satani wá, o si mu ọ̀rọ na ti a fọn si àiya wọn kuro. Awọn wọnyi pẹlu si li awọn ti a fun sori ilẹ apata; awọn ẹniti nigbati nwọn ba gbọ́ ọ̀rọ na, lojukanna nwọn a fi ayọ̀ gbà a; Nwọn kò si ni gbongbo ninu ara wọn, ṣugbọn nwọn a wà fun ìgba diẹ: lẹhinna nigbati wahalà tabi inunibini ba dide nitori ọ̀rọ na, lojukanna nwọn a kọsẹ̀. Awọn wọnyi li awọn ti a fun sarin ẹgún; awọn ti o gbọ́ ọ̀rọ na, Aniyan aiye, ati itanjẹ ọrọ̀, ati ifẹkufẹ ohun miran si bọ sinu wọn, nwọn fún ọ̀rọ na pa, bẹ̃li o si jẹ alaileso. Awọn wọnyi si li eyi ti a fún si ilẹ rere; irú awọn ti o gbọ́ ọ̀rọ na, ti wọn si gbà a, ti wọn si so eso, omiran ọgbọgbọ̀n, omiran ọgọtọta, omiran ọgọrọrun.

Àwọn fídíò fún Mak 4:14-20