Mak 4:1-9

Mak 4:1-9 YBCV

O si tún bẹ̀rẹ si ikọni leti okun: ọ̀pọ ijọ enia si pejọ sọdọ rẹ̀, tobẹ̃ ti o bọ́ sinu ọkọ̀ kan, o si joko ninu okun; gbogbo awọn enia si wà ni ilẹ leti okun. O si fi owe kọ́ wọn li ohun pipọ, o si wi fun wọn ninu ẹkọ́ rẹ̀ pe, Ẹ fi eti silẹ; Wo o, afunrugbin kan jade lọ ifunrugbin; O si ṣe, bi o ti nfunrugbin, diẹ bọ́ si ẹba ọ̀na, awọn ẹiyẹ si wá, nwọn si ṣà a jẹ. Diẹ si bọ́ sori ilẹ apata, nibiti kò li erupẹ̀ pipọ; lojukanna o si ti hù jade, nitoriti kò ni ijinlẹ: Ṣugbọn nigbati õrùn goke, o jóna; nitoriti kò ni gbongbo, o gbẹ. Diẹ si bọ́ sarin ẹgún, nigbati ẹgún si dàgba soke, o fun u pa, kò si so eso. Omiran si bọ́ si ilẹ rere, o si so eso, ti o ndagba ti o si npọ̀; o si mu eso jade wá, omiran ọgbọgbọn, omiran ọgọtọta, omiran ọgọrọ̀run. O si wi fun wọn pe, Ẹniti o ba li etí lati fi gbọ, ki o gbọ́.

Àwọn fídíò fún Mak 4:1-9