Nigbati Jesu jinde li owurọ̀ kutukutu ni ijọ kini ọ̀sẹ, o kọ́ fi ara hàn fun Maria Magdalene, lara ẹniti o ti lé ẹmi èṣu meje jade. On si lọ sọ fun awọn ti o ti mba a gbé, bi nwọn ti ngbàwẹ, ti nwọn si nsọkun. Ati awọn, nigbati nwọn si gbọ́ pe o ti di alãye, ati pe, on si ti ri i, nwọn kò gbagbọ. Lẹhin eyini, o si fi ara hàn fun awọn meji ninu wọn li ọna miran, bi nwọn ti nrìn li ọ̀na, ti nwọn si nlọ si igberiko. Nwọn si lọ isọ fun awọn iyokù: nwọn kò si gbà wọn gbọ́ pelu. Lẹhinna o si fi ara hàn fun awọn mọkanla bi nwọn ti joko tì onje, o si ba aigbagbọ́ ati lile àiya wọn wi, nitoriti nwọn ko gbà awọn ti o ti ri i gbọ́ lẹhin igbati o jinde.
Kà Mak 16
Feti si Mak 16
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Mak 16:9-14
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò