Mak 15:27-32

Mak 15:27-32 YBCV

Nwọn si kàn awọn olè meji mọ agbelebu pẹlu rẹ̀; ọkan li ọwọ́ ọtún, ati ekeji li ọwọ́ òsi rẹ̀. Iwe-mimọ si ṣẹ, ti o wipe, A si kà a mọ awọn arufin. Awọn ti nrekọja lọ si nfi i ṣe ẹlẹyà, nwọn si nmì ori wọn, wipe, A, Iwọ ti o wó tẹmpili, ti o si kọ́ ọ ni ijọ mẹta, Gbà ara rẹ, ki o si sọkalẹ lati ori agbelebu wá. Gẹgẹ bẹ̃li awọn olori alufa pẹlu, nwọn nsin i jẹ ninu ara wọn pẹlu awọn akọwe, wipe, O gbà awọn ẹlomiran là; kò le gbà ara rẹ̀. Jẹ ki Kristi, Ọba Israeli, sọkalẹ lati ori agbelebu wá nisisiyi, ki awa ki o le ri i, ki a si le gbagbọ́. Awọn ti a kàn mọ agbelebu pẹlu rẹ̀ si nkẹgan rẹ̀.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ