Mak 14:6-9

Mak 14:6-9 YBCV

Ṣugbọn Jesu wipe, Ẹ jọwọ rẹ̀ si; ẽṣe ti ẹnyin fi mba a wi? Iṣẹ́ rere li o ṣe si mi lara. Nigbagbogbo li ẹnyin sá ni talakà pẹlu nyin, ẹnyin le ma ṣore fun wọn nigbakugba ti ẹnyin fẹ; ṣugbọn emi li ẹnyin kó ni nigbagbogbo. O ṣe eyi ti o le ṣe: o wá ṣiwaju lati fi oróro kùn ara mi fun sisinku mi. Lõtọ ni mo wi fun nyin, Nibikibi ti a o gbé wasu ihinrere yi ni gbogbo aiye, nibẹ̀ pẹlu li a o si rò ihin eyi ti obinrin yi ṣe lati fi ṣe iranti rẹ̀.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ