Mak 13:28-31

Mak 13:28-31 YBCV

Nisisiyi ẹ kọ́ owe lara igi ọpọtọ; Nigbati ẹ̀ka rẹ̀ ba yọ titun, ti o ba si ru ewé, ẹnyin mọ̀ pe igba ẹ̃rùn sunmọ etile: Gẹgẹ bẹ̃ na li ẹnyin, nigbati ẹnyin ba ri nkan wọnyi ti nṣẹ, ki ẹ mọ̀ pe o sunmọ etile tan lẹhin ilẹkun. Lõtọ ni mo wi fun nyin, Iran yi kì yio rekọja, titi a o fi mu gbogbo nkan wọnyi ṣẹ. Ọrun on aiye yio rekọja: ṣugbọn ọ̀rọ mi kì yio rekọja.

Àwọn fídíò fún Mak 13:28-31