Mak 13:24-27

Mak 13:24-27 YBCV

Ṣugbọn li ọjọ wọnni, lẹhin ipọnju na, õrùn yio ṣõkun, oṣupá kì yio si fi imọle rẹ̀ hàn; Awọn irawọ oju ọrun yio já silẹ̀, ati agbara ti mbẹ li ọrun li a o si mì titi. Nigbana ni nwọn o si ri Ọmọ-enia ti yio ma ti oju ọrun bọ̀ ti on ti agbara nla ati ogo. Nigbana ni yio si rán awọn angẹli rẹ̀, yio si kó gbogbo awọn ayanfẹ rẹ̀ lati ori igun mẹrẹrin aiye jọ, lati ikangun aiye titi de ikangun ọrun.

Àwọn fídíò fún Mak 13:24-27