Mak 11:12-14

Mak 11:12-14 YBCV

Ni ijọ keji, nigbati nwọn ti Betani jade, ebi si npa a: O si ri igi ọpọtọ kan li òkere ti o li ewé, o wá, bi bọya on le ri ohun kan lori rẹ̀: nigbati o si wá si idi rẹ̀, ko ri ohun kan, bikoṣe ewé; nitori akokò eso ọpọtọ kò ti ito. Jesu si dahùn o si wi fun u pe, Ki ẹnikẹni má jẹ eso lori rẹ mọ́ titi lai. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si gbọ́ ọ.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ